Amos 1:13-15

13 aÈyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti Ammoni
àní mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà,
Nítorí wọn ti la inú àwọn aboyún Gileadi
kí wọ́n ba à lè fẹ ilẹ̀ wọn sẹ́yìn.
14Èmi yóò rán iná sí ara odi Rabba
èyí tí yóò jó àwọn ààfin rẹ̀ run
pẹ̀lú ìhó ayọ̀ ní ọjọ́ ogun,
pẹ̀lú ìjì líle ni ọjọ́ àjà.
15Ọba wọn yóò sì lọ sí ìgbèkùn
Òun àti àwọn ọmọ-aládé rẹ̀ lápapọ̀,”
ni Olúwa wí.
Copyright information for YorBMYO